BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
A ti gba mílíọ́nù márùndínlọ́gbọ̀n Náírà owó tí Ogogo gbé fún Ìmáàmù àgbà Ilaro padà - Ẹbí Ogogo
Imam agba Mustapha ló tan imole sì ọrọ naa lowuro ojo Aje níbi ayẹyẹ fidau fun Ologbe Taiwo Hassan Ogogo to waye lonii ọjọ Aje.
Ọ̀rọ̀ oyè Awujale tún gba ọ̀nà míì yọ, bí igbákejì alága ìdílé Funsegbuwa ṣe wọ́ àwọn èèyàn tó ya kúrò nínú ìdílé lọ sílé ẹjọ́, bèèrè N10bn
Ni ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ ni Oloye Fassy wọ awọn eeyan naa lọ siwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Ogun fun ẹsun ibanilorukọjẹ to si n beere fun owo itanran biliọnu mẹwaa naira gẹgẹ bi owo itanran.
Ìdí rèé tí Dangote fi ṣe àfikún owó epo bẹntiróòlù fún ìgbà mẹ́ta láàrin ọ̀sẹ̀ kan àti ipa rẹ̀ lórí aráàlú
Ile ifọpo Dangote sọ pe afikun owo epo bẹntiroolu naa ko ṣẹyin epo rọbi ọwọnlọwọn ti ileeṣẹ naa ti ra lati oke okun papaa julọ lasiko ti owo epo rọbi lọ soke lọja agbaye.
Àwọn ọmọ ogun wa nílẹ̀ Áfríkà ló dìde ìrànlọ́wọ́ láti kojú ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ẹ́ wáyé ní Niger - Russia ṣàlàyé
Niṣe ni iro ibọn n dun lakọlakọ, ti ado oloro si n dun kaakiri ni Niamey ni owurọ kutukutu ọjọ Abamẹta gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ.
Kí ló ṣe Adewale Eleso, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó fi ṣiṣẹ́ abẹ, ipò wo sì ni ìlera rẹ̀ wà?
Atẹjade ti agbẹnusọ agba fun ẹgbẹ oṣere ANTP, Ọmọọba Adejonwo Oluwafemi fi sita loju opo Facebook rẹ ni Eleso ti ṣiṣẹ abẹ tori egbo oju rẹ naa.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,00
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Ta ló ń pààrọ̀ orúkọ àwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú NDC lójú òpó àjọ elétò ìdìbò, bí INEC ṣe sẹ́ pé òun kọ́?
Alaga agba fun ẹgbẹ oṣelu NDC, Sẹnetọ Moses Cleopas Zuwoghe lo pariwo yii sita lọjọ Aiku ana, lẹyin ti ajọ INEC fi orukọ awọn oludije lẹgbẹ oṣelu sita.
Àlàyé rèé lórí ohun táwọn dókìtà nílé ìwòsàn LAUTECH ń bèèrè fún, bí ìyanṣẹ́lódì wọn ṣe wọ ọjọ́ mẹ́rin
Ẹgbẹ awọn dokita ile iwosan naa sọ pe awọn ko i tii gbọ ohunkohun lati ọdọ ijọba ipinlẹ Oyo lati ọjọ Ẹti, ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ti wọn ti gunle iyanṣẹlodi naa.
A ti ṣetán láti ṣàtìlẹ́yìn fún ìjọba lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ – OPC
Ọrọ yii lo jẹyọ lọjọ Abamẹta nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti n ṣe iranti idasilẹ ẹgbẹ ọhun lọdun mejilelọgọbọn sẹyin.
Wo àwọn ọ̀nà tí o lè gbà láti ṣọ́ owó ná lórí oúnjẹ lásìkò ọ̀wọ́ngógó yìí
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo ti n ṣe bi wọn ṣe mọ, ọpọ awọn mii lo ṣi n wa ọna lati ni owo diẹ lọwọ lẹyin ti wọn ba ra ounjẹ sile tan.
Kí ló mú kí ọkùnrin kan fi ọ̀bẹ pa èèyàn kan nílé sinimá l'Eko, tí ẹ̀mí òun náà fi bọ́? Àlàyé rèé
Ọkunrin kan ti wọn lo ti fa ifakufa sara ni wọn lo gun ẹṣọ aabo ile iworan naa titi to fi jade laye, to si tun ṣe ẹṣọ aabo miran leṣe, iyẹn lalẹ ọjọ Ẹti to kọja yii.
Àlàyé ohun tó fa ilẹ̀ rírì Nepal tó mú ẹ̀mí èèyàn 700 lọ
Ileeṣẹ iroyin China, CCTV, jabọ pe eeyan 16 lo ku lo ni Tibet nigba ti ọpọ ile ti wo lulẹ nibẹ.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Wo oúnjẹ méjìlá tó ń ran iṣẹ́ ọpọlọ àti ìròrí lọ́wọ́
Bi ọpọlọ ṣe jẹ kókó ohun ti ẹda fi n huwa, bẹẹ naa lo tun n kopa ninu idari ohun to n ṣẹlẹ ninu ara.
Fídíò, Ẹlẹ́mí èṣù làwọn ayálégbé míràn, àfi kí ìjọ̀ba yọwọ́ lọ́rọ́ onílé àti ayálégbé ní Nàìjíríà – Isaac Fayose, Duration 4,55
Ninu eto 'Nibo laye kọju si?' ti ọsẹ yii, eekan kan lawujọ, Isaac Fayose ni ko si ohun to yẹ ko kan ijọba nipa inọja laarin larinlọọdu ati ayalegbe.
Wo ìdí mẹ́ta tí akẹ́kọ̀ọ́ tí ilé ẹ̀kọ́ ti gbà wọlè le má rìí orúkọ rẹ̀ lójú òpó JAMB àtàwọn ìgbésẹ̀ tò yẹ kó o gbé
JAMB ninu alaye kan ti wọn gbe soju opo ayelujara X wọn ṣalaye pe o ṣeeṣe ki eeyan ti ile ẹkọ to ṣe idanwo lati lọ gba a wọle amọ ki wọn ma ri loju opo JAMB pe wọn ti gba a sile ẹkọ naa ati pe awọn nnkan mẹta lo maa n ṣokunfa rẹ.
Gómìnà Adeleke gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣe ìwádìí àwọn ìpànìyàn tó wáyé nílùú Ikire
Igbimọ oluwadii naa ti adajọ Majisireeti Ayokunle Shiyanbola ko sodi ni wọn yoo ṣewadii ohun to ṣokunfa ikọlu naa, ṣe agbejade iye ati orukọ awọn to fori sọta iṣẹlẹ naa, ṣewadii ohun to ikọlu ọhun ati boya o ni nnkan ṣe pẹlu iku to waye nibẹ.
Kí ni àrùn Diphtheria tó pa ọmọdé méje ní Imo, tó tún mú kí ilé ìwòsàn kún fọ́fọ́ ní Katsina?
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ojojumọ lawọn obi n ko awọn ọmọ wọn to lugbadi arun naa wa sile iwosan ọhun bayii, ẹsẹ ko si gba ero mọ.
Wo ìdí pàtàkí mẹ́rin tí Ààrẹ Tinubu kò ṣe fẹ́ kí ilẹ̀ Amẹ́ríkà fí àkọsílẹ̀ rẹ̀ nípà egbòogi olóró síta
Ninu iwe naa ni wọn ti sọ pe ofin anfaani si iroyin ati idaabo bo ẹtọ ọmọniyan yẹ ko jọba lori ṣiṣe afihan awọn akọsilẹ wọn, ati pe ko sẹnikẹni to fẹẹ mọ nipa rẹ.
Gómìnà Adeleke, mo kí ẹ kú oríire pé o wọlé fún sáà kejì àmọ́ ọ̀rọ̀ sì kù lẹ́yìn rẹ̀ - Oyebamiji, olùdíje gómìnà APC l'Osun
Oyebamiji nigba to n ba awọn ọmọ ẹyin ati alatilẹyin rẹ sọrọ fun igba akọkọ lẹyin eto idibo naa, iyẹn lọjọ Abamẹta to kọja, lo ti sọ pe oniruuru aṣemaṣe lo waye lasiko eto idibo naa.
Àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn tó kú níbí ìkọlù Ikire n bèèrè fín ìdájọ́ òdodo
Bi ẹ ko ba gbagbe, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti sọrọ lori ohun to ṣokunfa ikọlu to da ẹmi awọn eeyan legbodo, ti wọn si sọ abajade iwadii ti wọn ṣe.
Èèyà mẹ́ta farapa níbi tí ọlọ́pàá ti yìnbọn pa awakọ̀ lásìkò àyẹ̀wò
Asiko ti wọn lawọn ọlọpaa da awakọ naa duro lati yẹ ẹ wo, ṣugbọn ti ko duro, ni wọn sọ pe ọkan lara awọn ọlọpaa naa yinbọn fun un, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji ori irin.
Àìsàn jẹjẹrẹ kọlu àgbà òṣèrè mííràn
Dasofunjo rọ awọn ọkunrin kaakiri agbaye lati maa wa ni ikiyesara lori aisan jẹjẹrẹ to nii ṣe pẹlu nnkan ọmọkunrin, iyẹn prostrate cancer.
Wo ọ̀nà àrékérekè tuntun táwọn agbésùnmọ̀mí ń gbà r'owó ní Naijiria bàyìí yàtọ̀ sí gbígba owó ìtúsílẹ̀
ẹka kan to n ri si itọpinpin ibi towo n gba wọle, 'Nigeria Financial Intelligence Unit' (NFIU) ti sọ pe awọn agbebọn n fi ojoojumọ lekun si i nipa ọna ati maa rowo ṣiṣẹ laabi wọn ni.
Alága APC ìpínlẹ̀ Kogi tí agbébọn yìnbọn pa, ohun tí a mọ̀ rèé
Awọn to pa a naa ṣa deede ya jade lati inu igbo to wa nitosi, wọn si bẹrẹ si i yinbọn si awọn ọkọ to n lọ.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ṣé lóòótọ́ ni Kira, ọmọ Ogogo bímọ tuntun? Mọ̀lẹ́bí Ogogo sọ̀rọ̀ síta
Iroyin ibi naa n waye lẹyin ọjọ diẹ si iku baba wọn eleyi to mu ki ọpọ fẹ mọ boya lotitọ ni iroyin naa.
Awuyewuye tún bẹ́ sílẹ̀ lórí ìyọnípò olórí ilé aṣòfin Ondo
Iroyin fi kun pe awọn ọlọpaa lati olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lo tete ji giri sawọn janduku naa ki awọn aṣofin naa to le maa ba ipade wọn lọ.
Ọmọ ọdún 90 ni Ààrẹ Tinubu, Ó sì ń ṣàárẹ̀, ẹ̀rí tó dájú ń bẹ lọ́wọ́ mi - Atiku Abubakar, olùdíje ADC
Atiku ni ọjọ ori aarẹ ju eyi to n polongo fun gbogbo aye lọwọ yii ati wi pe ilera rẹ ko gbe iṣẹ akoso orilẹede Naijiria mọ.
Ọbalayé tó kéré jùlọ lágbáyé jáde láyé lẹ́ni ọdún 34
Ọdun mẹta lo ti gun ori oye lẹyin ipapoda baba rẹ lọdun 1995.
Wo àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìkọ̀wéfipòsílẹ̀ Ààrẹ NFF, Ibrahim Gusau
Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2026 ni Gusau kede pe oun ko ṣe mọ niluu Abuja.
Bí o ṣe lè di olówó gọbọi nípa títú àṣírí àwọn tó ń jí owó ìlú kó lọ sókè òkun
Alaga ajọ EFCC, Ola Olukoyede, lo sọrọ naa nibi ipade International Symposium on Economic Crime to waye ni Cambridge, nilẹ Gẹẹsi.
Tani Olohun ṣàlàyé ohun tó mú Sunday Igboho wá sílé rẹ̀, àti ọ̀rọ̀ tó bá ọ̀gá ọlọ́pàá Kwara sọ káwọn ọlọ́pàá tó wá fipá gbé e nílé tó lè kúrò lágbègbè rẹ̀
Ninu fidio ti Ta ni Oloun ṣe naa, eyi to ti so bandeeji mọ ọwọ to si fi yipo ọrun rẹ lo ti ni oun n gba itọju lọwọ latari bawọn ọlọpaa Kwara naa ṣe gídì oun.
Bílíọ̀nù mẹ́jọ Naira làwọn ajínigbé ti gbà lọ́wọ́ aráàlú láàrín ọdún 2025 sí 2026 - Ìwádìí
Ninu iwadii rẹ, o ni ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Boko Haram lo gba ida aadọrun (90%) awọn owo itusilẹ ti wọn kọ silẹ lẹkun ila oorun Ariwa, bi o tilẹ jẹ wi pe iṣẹlẹ ijinigbe atawọn ti wọn ji gbe pọ ju tiwọn lọ lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria.
Àwọn wo ni ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 'Black Axe' tí ọlọ́pàá àgbáyé mú fún jìbìtì orí ayélujéra káàkiri àgbáyé àti ní ìwọ̀ oòrùn Africa? Àlàyé rèé
Awọn ọlọpaa Interpol mu awọn eeyan naa ninu iṣẹ kan ti wọn doju rẹ kọ awọn ẹgbẹ ọdaran kaakiri Iwọ-Oorun Africa (West Africa).












































































